Ezekiel 32:7-20

7Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
8Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
ni Olúwa Olódùmarè wí
9Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
kò í tí ì mọ̀.
10Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.
11“ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Idà ọba Babeli
yóò wá sí orí rẹ,
12Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.
13Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.
14Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò
kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo,
ni Olúwa Olódùmarè wí.
15Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro,
tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.
Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
16“Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò. 19Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’ 20Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.
Copyright information for YorBMYO